Proverbs 5

Ìkìlọ̀ láti yàgò fún àgbèrè

1Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi,
kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi,
2Kí ìwọ sì lè ní ìṣọ́ra
kí ètè rẹ sì le pa ìmọ̀ mọ́.
3Nítorí ètè àwọn àjèjì obìnrin a máa sun bi oyin,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì kúnná ju òróró lọ.
4Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó korò ju òróǹró lọ,
ó mú bí idà olójú méjì.
5Ẹsẹ̀ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà ikú
ìgbésẹ̀ rẹ̀ lọ tààrà sí ibojì òkú.
6Kí ìwọ má ba à já ipa ọ̀nà ìyè;
ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla, ṣùgbọ́n kò tilẹ̀ mọ́.

7Nítorí náà, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ dẹtí sí mi,
kí ẹ̀yin kí ó má ṣe yàgò kúrò nínú ọ̀rọ̀ tí mo sọ.
8Rìn ní ọ̀nà tí ó jìnnà sí ti rẹ̀,
má ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
9Àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́
àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
10Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn,
kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora,
nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán
12Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó!
Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
13N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu,
tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá
ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”

15Mu omi láti inú kànga tìrẹ
Omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.
16Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà
àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?
17Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan,
má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.
18Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún;
kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ,
Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo,
kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkúgbà.
20Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà,
tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?

21Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa
Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò
22Ìwà búburú ènìyàn búburú ni yóò mú kó bọ́ sínú okùn;
okùn ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀ yóò sì dìímú.
23Yóò kú ní àìgba ẹ̀kọ́
ìwà òmùgọ̀ ara rẹ̀ yóò sì mú kí ó máa ṣìnà kiri.
Copyright information for YorBMYO